Source text in English | Translation by Ṣọla AGBOỌLA (#30038) |
The Beginning All in a moment, years ago, The boy I was became a man: Suddenly my life began! I saw the world before me— So That ploughman by his horses stands Sweating on the first hill's brow, Having left the riverlands Furrowed in the vale below, And sees a mountainside to plough, Barren rock to blunt his share, Thunder hanging in the air, And the black peak above him, bare, Waiting now. —Let him plough it if he dare! | Ìbẹ̀rẹ̀ Lọ́gán ni gbogbo rẹ̰̀ ṣẹlẹ̀, ní àwọn ọdún kan sẹ́yìn, Ọmọdékùnrin tí mo jẹ́ di ọkùnrin: Lójijì ìgbé-ayé mi bẹ̀rẹ̀! Mo rí ayé níwájú mi— Nítorí náà Atúlẹ̀ yẹn nítòsí èèkàn àwọn ẹṣin rẹ̀ Nlàágùn lórí ténté òkè àkọ́kọ́, Lẹ́yìn tí ó ti kúrò níbi olómi náà Ó la aporo ní àfonífojì ìsàlẹ̀, Ó sì nrí ẹsẹ̀ òkè láti tú, Aṣálẹ̀ orí àpáta láti lo irin iṣẹ́ rẹ̀ ní àlòyọ́, Ààrá nrọ̀ dẹ̀dẹ̀ nínú afẹ́fẹ́, Ṣónṣó orí òkè dúdú náà sì wà lókè rẹ̀, ó ṣí sílẹ̀ Ó wá ndúró wàyí. —Jẹ́ kí ó tú ílẹ̀ náà tí ó bá tó bẹ́ẹ̀! |